Yoruba Hymns- Oluwa 'kore, 'Wọ l'a yin
LYRICS:
1. Oluwa ‘kore, ‘Wo l‘a yin;
Ileri Re ‘gbani ko yeOrisi igba si nyipo,
Ododun kun fun ore Re;
L‘ojo oni, awa dupe,
Je k‘iyin gba okan wa kan
2. B‘akoko ‘rugbin mu wa yo;
B‘igba erun nmu oru wa;
‘Gba t‘ owo ojo ba nrinle;
Tab‘ igbati ‘kore ba pon,
‘Wo Oba wa l‘a o ma yin;
‘Wo l‘alakoso gbogbo won.
3. Ju gbogbo re lo, nigbati
Owo re fun opo kale
‘Gbati ohun ayo gb‘ ile
B‘eda ti nko ire won jo;
Awa pelu y‘o ma yin O
Oore Re ni gbogbo wa npin.
4. Oluwa ‘kore, Tire ni
Ojo ti nro, orun ti nran;
Irugbin ti a ngbin sile,
Tire l‘ogbon ti nmu dagba;
Otun l'ebun Re l‘ododun;
Otun n‘iyin Re l‘enu wa.
Great!
ReplyDeleteWhat is the English equivalent of this hymn
ReplyDelete