Friday, December 13, 2019

Olorun t'odun to koja

Yoruba Hymns-Ọlọrun t'ọdun to kọja



1. O lorun t‘odun t‘o koja
   Iret‘ eyi ti mbo;
   Ib‘isadi wa ni iji
   A t‘ile wa laelae.

2. L‘abe ojiji ite Re
   L‘awon eniyan Re ngbe,
   Tito l‘apa Re nikanso,
   Abo wa si daju.

3. K‘awon oke k‘o to duro,
   Tabi k‘a to d‘aye,
   Laelae IWO ni Olorun
   Bakanna, l‘ailopin!

4. Egberun odun l‘oju Re
   Bi ale kan l‘o ri;
   B‘iso kan l‘afemojumo
   Ki orun k‘o to la.

5. Ojo wa bi odo sisan,
   Opo l‘o si ngbe lo;
   Won nlo, won di eni ‘gbagbe
   Bi ala ti a nro ‘

6. Olorun t‘odun t‘o koja,
   Iret‘ eyi ti mbo,
   Ma s‘abo wa ‘gba ‘yonu de
   At‘ ile wa laelae.

No comments:

Post a Comment