Friday, December 13, 2019

Gbo bi Oluwa ti mbebe

Yoruba hymn- Gbọ bi Oluwa ti mbẹbẹ



LYRICS:

1. Gbo bi Oluwa ti mbebe,
   Ise wa fun gbogbo wa;
   Gbo bi Emi ti nwi pelu,
   Ipe na bayi pe:

      “Mo setan lati sise fun O Jesu,
        Emi de, ran mi;
        Mo nfe lati se ife Re ni pipe,
        Un o lo s‘ibit‘O ba ran mi
        Mo setan lati sise fun O Jesu
        Emi de, ran mi;
        Bi ona tile sokun, eru ko bami
        Mo se tan fun ise Jesu.

2. Ohun kan npe o nisiyi,
   Fi eti si ohun na;
   O nso si o l‘eti jeje,
   Je ipe na bayi pe.

3. Okan pupo nku n‘nu ese,
   Yara lati se ‘ranwo;
   ‘Tori akoko nkoja lo,
   So fun Jesu bayi pe.

No comments:

Post a Comment