Yoruba Hymns- Jesu Mo gbagbelebu mi
LYRICS:
1. Jesu, mo gb‘agbelebu mi
Ki nle ma to O leyin;
Otosi at‘eni egan,
‘Wo l‘ohun gbogbo fun mi
Bi ini mi gbogbo segbe
Ti ero mi gbogbo pin
Sibe, oloro ni mo je!
T‘emi ni Krist‘ at‘orun.
2. Eda le ma wahala mi,
Y‘o mu mi sunmo O ni;
Idanwo aye le ba mi,
Orun o mu ‘simi wa,
Ibanuje ko le se nkan
Bi ‘fe Re ba wa fun mi;
Ayo ko si le dun mo mi
B‘iwo ko si ninu re
3. Okan mi, gba igbala re;
Bori ese at‘eru;
F‘ayo wa ni ipokipo,
Ma sise lo, ma weyin,
Ro t‘emi t‘o wa ninu Re
At‘ ife Baba si o!
W‘Olugbala t‘O ku fun o
Omo orun mase kun.
4. Nje koja lat‘ ore s‘ogo
N‘nu adura on ‘gbagbo;
Ojo ailopin wa fun O,
Baba y‘o mu o de ‘be,
Ise re l‘aye fere pin
Ojo ajo re nbuse,
Ireti y‘o pada ‘sayo,
Adura s‘orin iyin.