Saturday, December 5, 2020

Yoruba Hymns-Fi Ibukun Rẹ tu wa ka


Lyrics 
 Fi ibukun Rẹ tu wa ka, 

1. Fi ibukun Rẹ tu wa ka, 
   Fi ayọ kun ọkan wa; 
   K‘olukuluku mọ ‘fẹ Rẹ
   K‘a l‘ayọ n‘nu ore Rẹ; 
   Tu wa lara tu wa l‘ara 
   La aginju aye ja. 

2. Ọpẹ at‘ iyin l‘a nfun Ọ
   Fun ihinrere ayọ; 
   Jẹ ki eso igbala Rẹ, 
   Pọ l‘ọkan at‘iwa wa; 
   Ki oju Rẹ, ki oju Rẹ 
   Ma ba wa gbe titi lọ 

3. Njẹ n‘igbat‘ a ba si pe wa 
   Lati f‘aye yi silẹ 
   K‘Angẹli gbe wa lọ s‘ọrun, 
   L‘ayọ ni k‘a j‘ ipe na; 
   K‘a si jọba, k‘a si jọba 
   Pẹlu Kristi titi lae. 
Amin. 

Saturday, December 21, 2019

Yoruba Hymns- Jesu Mo gbagbelebu mi


Yoruba Hymns- Jesu Mo gbagbelebu mi



LYRICS:


1. Jesu, mo gb‘agbelebu mi
   Ki nle ma to O leyin;
   Otosi at‘eni egan,
   ‘Wo l‘ohun gbogbo fun mi
   Bi ini mi gbogbo segbe
   Ti ero mi gbogbo pin
   Sibe, oloro ni mo je!
   T‘emi ni Krist‘ at‘orun.

2. Eda le ma wahala mi,
   Y‘o mu mi sunmo O ni;
   Idanwo aye le ba mi,
   Orun o mu ‘simi wa,
   Ibanuje ko le se nkan
   Bi ‘fe Re ba wa fun mi;
   Ayo ko si le dun mo mi
   B‘iwo ko si ninu re

3. Okan mi, gba igbala re;
   Bori ese at‘eru;
   F‘ayo wa ni ipokipo,
   Ma sise lo, ma weyin,
   Ro t‘emi t‘o wa ninu Re
   At‘ ife Baba si o!
   W‘Olugbala t‘O ku fun o
   Omo orun mase kun.

4. Nje koja lat‘ ore s‘ogo
   N‘nu adura on ‘gbagbo;
   Ojo ailopin wa fun O,
   Baba y‘o mu o de ‘be,
   Ise re l‘aye fere pin
   Ojo ajo re nbuse,
   Ireti y‘o pada ‘sayo,
   Adura s‘orin iyin.

Friday, December 13, 2019

E yo Jesu Joba

Yoruba Hymns- E yo Jesu Joba

https://youtu.be/Lrse2zXTYDA




LYRICS:


1. Eyo Jesu joba
   ‘Nu omo eniyan
   O da ara tubu
   O so won d‘om'nira:
   K‘esu koju s‘Om‘ Olorun,
   Lai f'ota pe, ise Re nlo


2. Ise ti ododo
   Oto, alafia
   Fun rorun aye wa,
   Yi o tan ka kiri
   Keferi, Ju won o wole
   Won o jeje isin yiye

3. Agbara l‘owo Re
   Fun abo eni Re,
   Si ase giga Re;
   L‘opo o kiyesi
   Orun ayo ri 'se Re
   Ekusu rere gb‘ofin Re

4. Irugbin t‘orun yi
   O fere d‘igi nla;
   Abukun wukara
   Ko le saitan kiri;
   Tit‘ Olorun Omo tun wa
    Ko le sailo, Amin! Amin!

Gbo bi Oluwa ti mbebe

Yoruba hymn- Gbọ bi Oluwa ti mbẹbẹ



LYRICS:

1. Gbo bi Oluwa ti mbebe,
   Ise wa fun gbogbo wa;
   Gbo bi Emi ti nwi pelu,
   Ipe na bayi pe:

      “Mo setan lati sise fun O Jesu,
        Emi de, ran mi;
        Mo nfe lati se ife Re ni pipe,
        Un o lo s‘ibit‘O ba ran mi
        Mo setan lati sise fun O Jesu
        Emi de, ran mi;
        Bi ona tile sokun, eru ko bami
        Mo se tan fun ise Jesu.

2. Ohun kan npe o nisiyi,
   Fi eti si ohun na;
   O nso si o l‘eti jeje,
   Je ipe na bayi pe.

3. Okan pupo nku n‘nu ese,
   Yara lati se ‘ranwo;
   ‘Tori akoko nkoja lo,
   So fun Jesu bayi pe.

Olorun t'odun to koja

Yoruba Hymns-Ọlọrun t'ọdun to kọja



1. O lorun t‘odun t‘o koja
   Iret‘ eyi ti mbo;
   Ib‘isadi wa ni iji
   A t‘ile wa laelae.

2. L‘abe ojiji ite Re
   L‘awon eniyan Re ngbe,
   Tito l‘apa Re nikanso,
   Abo wa si daju.

3. K‘awon oke k‘o to duro,
   Tabi k‘a to d‘aye,
   Laelae IWO ni Olorun
   Bakanna, l‘ailopin!

4. Egberun odun l‘oju Re
   Bi ale kan l‘o ri;
   B‘iso kan l‘afemojumo
   Ki orun k‘o to la.

5. Ojo wa bi odo sisan,
   Opo l‘o si ngbe lo;
   Won nlo, won di eni ‘gbagbe
   Bi ala ti a nro ‘

6. Olorun t‘odun t‘o koja,
   Iret‘ eyi ti mbo,
   Ma s‘abo wa ‘gba ‘yonu de
   At‘ ile wa laelae.

Oluwa 'kore, 'Wo l'a yin

Yoruba Hymns- Oluwa 'kore, 'Wọ l'a yin





LYRICS:

1. Oluwa ‘kore, ‘Wo l‘a yin;
   Ileri Re ‘gbani ko ye
   Orisi igba si nyipo,
   Ododun kun fun ore Re;
   L‘ojo oni, awa dupe,
   Je k‘iyin gba okan wa kan

2. B‘akoko ‘rugbin mu wa yo;
   B‘igba erun nmu oru wa;
   ‘Gba t‘ owo ojo ba nrinle;
   Tab‘ igbati ‘kore ba pon,
   ‘Wo Oba wa l‘a o ma yin;
   ‘Wo l‘alakoso gbogbo won.

3. Ju gbogbo re lo, nigbati
   Owo re fun opo kale
   ‘Gbati ohun ayo gb‘ ile
   B‘eda ti nko ire won jo;
   Awa pelu y‘o ma yin O
   Oore Re ni gbogbo wa npin.

4. Oluwa ‘kore, Tire ni
   Ojo ti nro, orun ti nran;
   Irugbin ti a ngbin sile,
   Tire l‘ogbon ti nmu dagba;
   Otun l'ebun Re l‘ododun;
   Otun n‘iyin Re l‘enu wa.

Emi ‘ba n’ egberun ahon

Yoruba Hymns-Emi ‘ba n’ ẹgbẹrun ahọn

Click: https://youtu.be/0KFwPgOhw4U




LYRICS:

1. Emi ‘ba n‘egberun ahon,
   Fun ‘yin Olugbala,
   Ogo Olorun Oba mi,
   Isegun ore Re.

2. Jesu t‘o seru wa d‘ayo
   T‘o mu banuje tan
   Orin ni l‘eti elese
   Iye at‘ ilera

3. O segun agbara ese
   O da onde sile,
   Eje Re le w‘ eleri mo,
   Eje Re seun fun mi

4. O soro, oku gb‘ohun Re,
   O gba emi titun,
   Onirobinuje y‘ayo,
   Otosi si gbagbo

5. Odi, e korin iyin Re,
   Aditi, gbohun Re;
   Afoju, Olugbala de,
   Ayaro, fo f‘ayo

6. Baba mi at‘Olorun mi,
   Fun mi ni ‘ranwo Re;
   Ki nle ro ka gbogbo aye,
   Ola oruko Re.

Thursday, December 12, 2019

Ekun ko le gba mi

Yoruba Hymns- Ẹkun ko le gba mi

Click: https://youtu.be/TRmu7FHwJVM



LYRICS:


1. Ekun ko le gba mi,
   Bi mo le f‘ekun we ‘ju;
   Ko le mu eru mi tan,
   Ko le we ese mi nu;
   Ekun ko le gba mi,

       Jesu sun, O ku fun mi.
       O jiya l‘ori igi,
       Lati so mi d‘omnira,
       On na l‘O le gba mi.

2. Ise ko le gba mi,
   Ise mi t‘o dara ju,
   Ero mi t‘o mo julo,
   Ko le so ‘kan mi d‘otun
   Ise ko le gba mi.

3. ‘Duro ko le gbami,
   Eni t‘o junu ni mi,
   L‘eti mi l‘anu nke pe,
   Bi mo ba duro, un o ku;
   Duro ko le gba mi.

4. Igbagbo le gba mi,
   Je ki ngbeke l‘Omo Re
   Je ki ngbekele ‘se Re
   Je ki nsa si apa Re,
   Igbagbo le gba mi.

Oluwa ran mi ni 'ṣẹ Aleluya


Yoruba Hymns -Oluwa ran mi ni 'ṣẹ Aleluya

 Click : https://youtu.be/tE2-o1gO8R8


Lyrics

1. Oluwa ran mi ni ‘se, Aleluya!
   Iwo ni uno je ise na fun;
   A ko s‘inu Oro Re, Aleluya!
   P‘eni t‘o ba wo Jesu y‘o ye.

       Wo, k‘o ye, Arakunrin,
       Wo Jesu ki o si ye,
       A ko s‘inu Oro Re, Aleluya!
       P‘eni t‘o ba wo Jesu y‘o ye.

2. A ran mi n‘ise ayo, Aleluya!
   Uno j‘isena fun o ore mi;
   Ise lat‘ oke wa ni; Aleluya!
   Jesu SO, mo mo pe oto ni.

3. A n‘owo iye si O, Aleluya!
   A o fi ‘ye ailopin fun O;
   T‘o ba wo Jesu nikan, Aleluya!
   Wo o, On nikan l‘o le gbala. .