Lyrics
Fi ibukun Rẹ tu wa ka,
1. Fi ibukun Rẹ tu wa ka,
Fi ayọ kun ọkan wa;
K‘olukuluku mọ ‘fẹ Rẹ
K‘a l‘ayọ n‘nu ore Rẹ;
Tu wa lara tu wa l‘ara
La aginju aye ja.
2. Ọpẹ at‘ iyin l‘a nfun Ọ
Fun ihinrere ayọ;
Jẹ ki eso igbala Rẹ,
Pọ l‘ọkan at‘iwa wa;
Ki oju Rẹ, ki oju Rẹ
Ma ba wa gbe titi lọ
3. Njẹ n‘igbat‘ a ba si pe wa
Lati f‘aye yi silẹ
K‘Angẹli gbe wa lọ s‘ọrun,
L‘ayọ ni k‘a j‘ ipe na;
K‘a si jọba, k‘a si jọba
Pẹlu Kristi titi lae.
Amin.